Wednesday, April 2, 2014

Ọ̀rọ̀ Nigerians...

Ọrọ Nigerians ati Ìjọba dabi ọrọ Ọba to n dọbalẹ fun ijoye—sebi awa ara ilu l’ọba, awọn ti a dìbòyàn ni ìjòyè— Ọba wa n dọbalẹ fun ijoyè, igi da! O yẹ ki a mọ wipe bi a ò bá diboyan wọn, wọn ò ni wọlé—kini mo n sọ lẹnu gan na, sebi awọn were ti mọ ẹni to ma wọle lai tii dibo. Sugbọn sibẹsibẹ, kosi ẹni to wọle to wa ni ara ilu ò dibo fun ohun—ara ilu l’ọba.

Bi wọn gbà wipe a dibo fun wọn ki wọn tó wọle—tani ó yẹ kó gbadun ju? Ọba abi ijoye? Onile tabi alejo? Agbani sísé tabi òsìsẹ̀? Ọ̀rọ̀ yi tojusumi o—Se Oloselu l’ọba tabi ara ilu? Bi wọn ba n wa ipò, wan dabi dọ̀dọ̀yọ̀, ti wọn ba gba ipò tan wan dabi Kiniun.

Bi wọn ba n lọ ni títì, gbogbo ọ̀nà ni wọn ma n tì pa—wọn ò ni jẹ ki onirin ó rìn. Bi wọn ba fẹ campaign, Yorùbá ni wọn ma n sọ, ti wọn ba ti wọle tan, Oyinbo ni kùrà. Aimoye oloselu lori twitter bayi o, ẹjẹ ki wọn wọle tan—o digba! Sebi igba kan ni GEJ wà lori twitter at faacebook—iyẹn nigba ti ò tii ni bàtà-- ọwọ ti GEJ ti tẹ èkù ida bayi o. Ààrẹ agbaye ni Obama, sibẹsibẹ o si n ba ara ilu sọrọ lori twitter, sé GEJ n sisẹ ju Obama lọ ni?

Ọgbẹni Reno Omokri, ki ni anfani orogbo rẹ na? Sé ọ̀tá ara ilu loye ki o jẹ abi abẹnugan fun ìjọba? A kii p’eni l’ólè kó tun ma gbe ọmọ adiyẹ jó—se aye ni awọn oloselu yi njẹ bayi? Emi ò ni oloselu kankan bawi bikose awa ara ilu ti a n ta ọjọ ọla wa notiri owó. ọmọ ẹlẹran wa n jeegun, ọmọ alasọ wa n wọ akisa.   

Ẹ ròó re o!

No comments:

Post a Comment