Bíbélì sọ fun wa wipe ki a fẹ́ ẹnikeji wa gẹ́gẹ́ bi ara wa—njẹ ìwọ ni ìfẹ́ ẹnikeji rẹ bi? Bi Gómìnà bá nifẹ awọn ará ilu gẹ́gẹ́ bi ara rẹ̀, kòní fìyà jẹ wọn. Ìfẹ́ làkójá òfi—òsìkà ati ọ̀dájú ni ẹni ti ò ba nifẹ ọmọ’ nikeji rẹ̀. Gbogbo awọn tó n kówójẹ l’orilẹ èdè yi ò nifẹ Nigeria rárá—òsìkà ati ọ̀dájú niwọn. Owó tí ó yẹ ki gbogbo wa ná, ìwọ nikan fẹ́ dána—olórí burúkú ni ọ́ o. Èmi ti yí àdúrà mi pada o—èmí ò le wa máa gbadura fún awọn ọ̀tá mi—Adura mi fun orilẹ ede Nigeria ni wipe ki Ọlọrun pa gbogbo awọn to n niwa lara. ọkankan ni ọmọ ọwọ̀ nwọ, jẹ ki awọn ọ̀tá orilẹ èdè yi bẹ̀rẹ sii wọ́kú dànù.
follow me on twitter: @maxiculture
No comments:
Post a Comment