Wednesday, April 2, 2014

Ìtàn Ìyá Ehoro

Ìyá Ehoro ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ tuntun ni, gbogbo àwọn ẹranko igbó sì lọ kí i kú ewu. Àkókò yìí ṣe pàtàkì fún ìyá Ehoro nítorí pé gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú tán tẹ́lẹ̀. Ó se oúnjẹ púpọ̀, àwọn ẹranko sì ń jẹ, wọn ń mu. Ṣùgbọ́n kinní kan ń bà wọ́n lẹ́rù. Bí wọ́n bá ti wọlé, tí wọ́n sì kí ìyá ọmọ tuntun, kì í dá wọn lóhùn, ojú ló máa ń mọ́ wọn. Ọ̀rọ̀ náà kò yé wọn.

Wọ́n wáá pinnu láti gba àdúrà àgbàpọ̀. Wọ́n ní kí Túùpú Ẹlẹ́dẹ̀ Ẹgàn ṣaájú wọn nínú àdúrà. Túùpú ní kí gbogbo ẹranko máa wí tẹ̀lé òun bí òun bá ti ń gbàdúrà, kí wọ́n sì máa ṣe àmín. Túùpú bẹ̀rẹ̀, ó ní “Kí Olódùmarè, ọba àánú, olùṣọ́ ẹranko àti ẹyẹ nínú igbó dákun máa dáàbo tí ó lágbára bo Ìyá Ehoro àti àwọn ọmọ rẹ̀ ní àkókò yí tí ó kún fún ewu. Àmín. Àwọn yòókù náà ń ṣe Àmín tẹ̀lé Túùpú. Wọ́n gbàdúrà títí. Ṣùgbọ́n Túùpú Ẹlẹ́dẹ̀ Ẹgàn ṣàkíyèsí pé Ìyá Ehoro kò bá wọn gbàdúrà, kò sì ṣe Àmín kankan. Ṣé ẹ mọ̀ pé bí àwọn ẹranko bá ń gbàdúrà, àwọn kì í dijú. Ó léwu! Túùpú dá àdúrà dúró. Ó wáá bi Ìyá Ehoro pé kín lódé tí kò fi bá wọn gbàdúrà, tí kò sì ṣàmí àdúrà, ṣebí òun ló bímọ? Ìyá Ehoro mọ́ gbogbo wọn lójú tákí, inú bí i, ó ní “Ẹ̀yin alágàbàgebè gbogbo wọ̀nyí. Ẹ róòótọ́ nílẹ̀ ẹ ẹ̀ le sọ! Ṣé àdúrà òtítọ́ ni ẹ ń gbà yẹn? Taa lẹ ń gbàdúrà sí?” Gbogbo wọn dákẹ́ lọ gbáà. Ẹnu yà wọ́n! Ẹfọ̀n ní àdúrà gidi ni a ń gbà, Olódùmarè ni a sì ígbàdúrà sí.

Ìyá Ehoro dáhùn, ó ní “Ṣebí ẹ mọ̀ pé Olódùmarè ló fún mi lọ́mọ, ẹ sì mọ̀ pé rere ni Ọlọ́run, kì í ṣe ibi. Kò níí fún ẹranko lọ́mọ tán kí ó tún máa pa á.” Àwọn ẹranko ní lóòótọ́ ni. Ìyá Ehoro wáá ké mọ́ wọn, ó ní “Ẹ ń kanrí mọ́lẹ̀, ẹ ń gbọnra pìtìpìtì, ṣebí ẹ mọ ẹni tó ń pa yín lọ́mọ, à bí ẹ ẹ̀ mọ̀ ọ́n? Ọdẹgbárò, ọmọ Ògúndélé ni kí ẹ lọọ bẹ̀, kò yé fi ìbọn rẹ̀ pa yín lọ́mọ mọ́ o.

Àwa náà níláti wá àwọn Ògúndélé ilé ayé tí wọ́n fẹ́ẹ́ pa àṣà wa run. Kì í ṣe ọ̀rọ̀ eré o. A kò le jókòó tẹtẹrẹ kí àwọn ọmọ wa sì sọ Yorùbá tì! Àṣà yàtọ̀ sí ẹ̀sìn o. Ó le jẹ́ mùsùlùmí gidi, kí o sì jẹ́ ọmọ Yorùbá rere. O le jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kírísítì kí ó sì máa sọ Yorùbá tó dára. Ọlọ́run ló fún wa ní àṣà tiwa o. A kì í ṣe ọmọ burúkú o. Ẹ̀yin olóṣèlú wa ẹ múra sí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ èdè Yorùbá o. Dandan ni o.

No comments:

Post a Comment