Friday, March 28, 2014
Awọn Fashion Shows!
Ẹkaarọ o-- ọ̀rọ̀ kan ti wà lọ̀kàn mi lati bii ọjọ mẹta sẹyin, ẹdákun ẹ jẹ kin sọ funyin. ọ̀rọ̀ nipa ‘Nigeria Fashion week’, ‘Lekki Fashion show’ ati gbogbo awọn ‘fashion shows wọnyi ni. Ohun ti ó n kọmílóminú ni wipe, bawo lẹ se pe inkan ni ‘Nigeria Fashion show’ ti o jẹ wipe asọ oyinbo lẹ n polówó? Se Nigeria ò ni asọ tiwọn ni? Tẹni n tẹni, tàkísà n tààtàn—‘Fashion Show’ ti ò bá ti polówó asọ Nigeria kii se ojulowo ‘fashion show’. Inú ìwé wo ni ká kọ eleyi sí—ti wọn ba tun beere wipe ‘what are you wearing?’ wèrè á ni ‘Versace’, o báà wọ ‘Ferrari’ ẹrú oyinbo ni ọ́.
Emi ò kin se ‘Fashion designer’ sugbọn mo mọ wipe ọpọlọpọ àrà ni a lè fi asọ tiwantiwa dá. Emi rò wipe idi ti wọn fi n peni ‘Nigeria Fashion show’ ni lati fi awọn asọ Nigeria hàn wá ni—mi o mọ wipe pupọ ninu awọn ‘fashion designers’ ni ò ni ọpọlọ ati fi asọ tiwantiwa dárà ti yááyì. ‘Fashion’ kii se fun ẹ̀yà kan. ‘Fashion’ kii se fun oyinbo nikan èwo wá ni oríburúkú ti ẹ n bááká?
Ẹni ba ta ara ile rẹ lọ́pọ̀, kòlè rira lọ́pọ̀ mọ o—asiko ti tó lati pe Àró ati Ọ̀dọ̀fin inu yin-- ẹ bẹrẹ sii se ohun ti o tọ-- ẹ bẹrẹ sii fi asọ tiwantiwa na dara ti o dara—kii se eleyi ti si ọmú silẹ o-- ẹjọwọ bi ẹ bá ni ‘handle’ awọn ‘fashion show’ wọnyi, ẹ fi fun mi- ọ̀rọ̀ wà.
Ire o!
If you want translations, Holla lekanddream@yahoo.com
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment