Ni ọdún 2010, mo
sin ilẹ̀ baba mi, èyí tin jẹ́ àgùnbánirọ̀ (NYSC) ni
ilu Ilesha ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀sun. Ọlágúnsóyè Oyinlọlá
ni Gómìnà ni ìgbà ti mò nwi yi. Ni ọ̀sán ọjọ́
kan ni mo wà níwájú ilé mi—sàdédé ni mo
gbọ́ ìró ìlù ati ijó— àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀
si tú jade sí títì, wọ́n n kọrin. Sèbí bí ò bá
ní ìdí, awọn àgbà ni obìrin kì íjẹ́
Kúmólú. Ni ọjọ́ ti mò n sọ yi, ìròyin ò tó àfojúbà—òpópónà Òsogbo sí Ilesha dàbí ọjà—bí ìgbà ti ààrẹ orílẹ̀-èdè
bá n w’ọ̀lú—Sé Ọbasanjọ lo n b’ọ̀wá ni? Wọn ni rárá. Nítoríwípé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ò lóùnkà, ijó n p’ajó jẹ, awọn eniyan fi sọ́ọ̀bù wọn sílẹ̀, wọn tú jade si oju títì. Sèbí àìsí níbẹ̀ làì báwọn dási, èmi pàápàá bẹ̀rẹ̀sí ijọ́, mo tun n tọpinpin
ẹni ti wọn n se eleyi fun. Ki n tó s’ẹ́jú
pẹ́, mo rí ọgbẹni kan to wọ asọ funfun, tin juwọ si ogun-lọ́gọ̀ awọn eniyan—Tani eleyi? Wọn ni ọgbẹni
Raufu Arẹ́gbẹ́sọlá ni orukọ rẹ njẹ—sé gómìnà ni? Wọn ni rárá—Sé Ààrẹ Orilẹ-èdè
ibìkan ni? Wọn ni rárá — mo ni èwo niti
Ajá ninu pínpín obì nitoriwipe ìran Ajá kì íjẹ obì—wọn ni ogbẹni díje fun ipò
gómìnà, sùgbọn awọn kan n gbe inú òkùnkùn
t’afà si ìmọ́lẹ̀, wọn ò fẹ́ kí ó w’ọlé.
Mo ní, e wo ibí ná, ènìyàn kọ̀ d’íje lásán ni gbogbo ayé wá pàdé rẹ̀ bayi , bí ó bá wá wọlé nkọ? Wọn ni Arẹ́gbẹ́ s’ènìyàn, wọn ni kì íse
eniyan lásán—wọn ni Arẹ́gbẹ́ kì íse ẹni yẹpẹrẹ. Mo ní óyá ẹ tu pẹ̀pẹ́ ọ̀rọ̀—ìgbàtí wọ́n sọ
oun ti Arẹ́gbẹ́ ti se fun wọn tán, èmi pàápàá bẹ̀rẹ̀sí paruwọ, mo n jó, mo n yọ̀. Lati ọjọ́ náà ni mo ti yan Ọ̀gbẹ́ni
Raufu Arẹgbẹsọla gẹ́gẹ́ bíi àwòkọ́se fún mi—àwòkọ́se gidi l’ọ̀gbẹ́ni.
Kò pẹ́ púpọ̀ ni mo parí NYSC tí
mo sì padà sí Ìlu-Èkó. Lẹyin èyí ni
ile ẹjọ́ dá ẹjọ́ tí gbogbo ayé n retí—wọn ni Ọ̀gbẹ́ni ló wọlé ninu ìdìbò ipò gómìnà náà—mi ò ní ànfàní lati sí ní Ipinlẹ Ọsun ni ọjọ́ ti mò n sọ
yii, sugbọn mo gbọ́ ìròyìn. Wọn ni Ipinlẹ Ọsun
dàbí àlùjọ́ná níbití awọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún ti n kọrin lai dákẹ́—wọn ni ojú ọjọ́ dàbí ìgbàti Elédùà bá rọ òjò ìbùkún kí gbogbo eniyan wa ma yàá—Nitoriwipe gbogbo
eniyan ló mọ̀ wipe ìgbà ọ̀tun ti
dé—wọn ni ayé daadé!
Ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀sí bà mí—kíni tèmi níbẹ̀? Ọ̀gbẹ́ni kì íse ará-ilé mi, èmi kì íse ọmọ
Ipinlẹ Ọsun—síbẹ̀ ẹ̀rù n bàmí nitoriwipe ìgbẹ́kẹ̀lé awọn ará ìlú sí Ọ̀gbẹ́ni pọ̀ lápọ̀jù—mo sì ti polongo Ọgbẹni si awọn ará ile mi gẹ́gẹ́ bi ẹni
ti mo n wò kọ́se—awọn eniyan mọ̀ wipe Arẹgbẹsọla
ni ‘Role model’ mi. Àìsàn tó bá ti bá ojú, ó ti bá gbogbo ara àti wipe ìlẹ̀kẹ̀ kì íjá k’ótún pé mọ́.
Ẹyin ènìyàn mi, lẹyin ọdún mẹta ó lé díẹ̀, ẹ̀rù ò bà mí mọ́ o. Ọ̀gbẹ́ni Rauf Arẹ́gbẹ́sọlá t’ọ́kùnrin o—akínkanjú ni Arẹ́gbẹ́, àwòkọ́se gidi sì ni pẹ̀lú. A kii gbé odò ó
jiyàn bi ọsẹ hó tàbí kò hó—ẹ w’olẹ̀, ẹ w’ẹnu
ọkọ́—Arẹgbẹ kii se gómìnà lásán— Ó mọ ohun tí ará ilu nfẹ, ó sì n sé fun wọn.
Ìkíní, ẹ jẹ́ k’áwo ètò ẹ̀kọ́—gbogbo wa ló mọ̀ wípé ẹ̀kọ́ se pàtàkì, ẹni ti ò bá l’ẹkọ, Irú wọn ló ma
n s’ẹrú ẹgbẹ́ bó bá d’ọ̀la—ẹnití ẹ̀kọ́ rẹ̀
ò bá kún ojú òsùwọ̀n ní íse ‘sir’ fún ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lọ́jọ́ iwájú—Ẹ̀kọ́ se kókó fún ìlọsíwájú ipinlẹ ati orílẹ-èdè lapapọ. Ẹ
dákun, ẹ w’obí ná—Arẹ́gbẹ́ mọ rírì ẹ̀kọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀. Ọ̀gbẹ́ni ni ẹ̀kọ́ ti kọjá k’ámá fi sọ́ọ̀kì k’ọsẹ́
si ara ògiri-- ẹ̀kọ́ ti di ayélujára. Àsìkò kọ̀npútà (Computer) lawà bayi—ìgbà
l’asọ, ìgbà l’ẹ̀wù, ẹni ti ò bá se oun ti awọn ẹgbẹ́ rẹ̀ nse nígbà t’óyẹ, olúwa
rẹ̀ ma n k’ábámọ n’ígbẹ̀yìn ni. L’óde òní, ẹni tí ò bá ni ìmọ̀ ẹ̀rọ ayélujára,
ó dàbí alákọ̀wé ti kò ni ‘biro’ ni— ó ma n nira fun irú wọn lati ri isẹ́, ó tún
ma n nira fún irú wọn lati b’ẹ́gbẹ́jọ. Ọ̀gbẹ́ni mọ̀ wípé kékeré lati n p’ẹ̀ka
ìrókò, tí ó bá dàgbà tán, a gbodidi ọmọ lọ́wọ́ ẹni.
Ọ̀gbẹ́ni pín ẹ̀rọ kọ̀npútà ‘Ọpọ́n ìmọ̀’ fún awọn ọmọ girama l’ọfẹ--
bí mo se n kọ ìwé yi, 28, 000 ọpọ́n ìmọ̀
ni wọn ti pín ninu 32, 000 tíwọ́n fẹ́ pin fun sáà yi-- ẹjọ̀wọ́ ẹ wá bámi w’ojú ayé olósèlú tòótọ́—150,
000 ọpọ́n ìmọ̀ ni ìjọba ní àjọrò pẹ̀lú
awọn ilé isẹ́ kan ni China lati pín-- Ọ̀gbẹ́ni wá sọfún wọn wípé; ẹ̀yin agbasẹ́se
lati China, ẹ má fún mi l’ẹ́ja, ẹ kọ́mi bi wọ́n se n p’ẹja. Ọ̀gbẹ́ni sọfún wọn
wipe ninu 150, 000 ọpọ́n ìmọ̀ ti a
fi àdéhùn sí, ẹ lọ kó 50, 000 wá lati ilu yín, 100, 000 tí ó kù, ẹ wá tò-wọ́n-jọ
ni ipinlẹ Ọsun— ìlọsíwájú ninu ètò ọrọ̀ ajé ati ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé ni èyí túmọ̀sí—Arẹ́gbẹ́
s’ènìyàn o.
Àwọn àgbà ni ọ̀kànkàn, èjèjì là n
y’ọsẹ̀ l’ékù—bí a bá ni ki a sọ gbogbo ohun ti Ọ̀gbẹ́ni Rauf Arẹ́gbẹ́sọla se
láàrin ọdun mẹta-- ẹ ma jẹ kin tàn yín, ọ̀rọ̀ pọ̀ níbẹ̀. Sugbọn ki n to m’ẹ́nu
l’éwọ́ fún tòní-- ẹ jẹ́ kin sọ ìrírí mi pẹ̀lú Ọ̀gbẹ́ni níwọ̀n osù kan sẹ́yìn. Mo
ni ọ̀rọ̀ kan ti mò n bá World Bank sọ̀rọ̀ lé lórí-- ọ̀rọ̀ nípa ìgbélárugẹ èdè
ati àsà ilẹ̀ adúláwọ̀ ni. World Bank ni kin lọ wá ìjọba ìpínlẹ̀ lati bá sowọ́pọ̀
lati gbé isẹ́ na wá síwájú wọn. Èmi ò mọ ẹnikẹ́ni tin s’èjọba lọ́wọ́—mo dààmú
títítí. Ní ọ̀sán ọjọ́ kan, ọ̀rẹ́ mi Káyọ̀dé
fún mi ni e-maili Ọ̀gbẹni, mo sì kọ lẹ́tà si. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, mo ri èsì-- ẹwábí
ná, gómìnà melo lólè sèyí? Arẹ́gbẹ́ s’ènìyàn, ẹ jẹ́ kó wọlé lẹ́ẹ̀kan si—ókù ni
ìbọn n ró! Mo sẹ̀sẹ̀ n m’ẹ́yẹ bọ̀ lápò lórí akitiyan Ọ̀gbẹ́ni Rauf Arẹ́gbẹ́sọlá
ni—Arẹ́gbẹ́ s’ènìyàn o!
Ọlálékan Fábílọlá
No comments:
Post a Comment